Oro Nipa Ise Pataki

Frankin Furnace Archive, Inc. bere ise pataki lati muki aiye toro fun Awon onise ona to joju.

(B) IWE ITAN KUKURU NIPA FRANKLIN FURNACE

A da Franklin Furnace sile ni odun 1976 lati se iranlowo fun awon eniti nya aworan ti nwon si yan ikede gege bi ona ti nse ise won lona ti nwon nfe, ti ko si iranlowo ti o wa lati awon ikojo awon eni ti nya aworan. Lati isedale ni Franklin Furnace ti nlo agbara re lati doju ko ona meta ti o fi nse akoso Ikojopo iwe awon ayaworan; ise aworan fun awon alakobere ni aworan yiya; ifihan ise aworan ti a se fun igba aipe; ise aworan ti a se ni ojukanna lati owo awon ayaworan tin won wa in igba kanna, ati iwe ti a fi se asehan ni ojo pipe ati ni akoko yi ati aworan ti ki baje.

Lati ogun odun sehin, ni okiki Franklin Furnace ti kan kari gbogbo America ati gbogo agbaiye fun oye ati imo awon ayaworan ti nwon fi apere tuntun lele; Franklin Furnace ti ko ise awon 20 th Century ise ara, Franklin Furnace si ti ndide fun gbogo iranlowo awon ayaworan ati lati ripe won se gbogbo nkan ti won nfe laiberu gege bi ase kosile ninu Iwe Itunse Akoko (First Amendment).

Awon ayaworan ti nwon koko fi ise won han ni Franklin Furnace ni: Ida Applebroog, Guillaume Bijl, Dara Birnbaum, Willie Cole, James Coleman, Jenny Holzer, Barbara Kruger, Matt Mullican, Krysztof Wodiczko; awon alasehan ti nwon ti nwon ti ipase Franklin Furnace bere ise won ni: Eric Bogosian, David Cale, Karen Finley, Guillermo Gómez-Pena, Robbie McCauley, Theodora Skipitares, Michael Smith, ati Paul Zaloom. Lafikun, ni ipase Franklin Furnace ni awon olokiki alasehan lori aworan gege bi Vito Acconci, Laurie Anderson, Carl Andre, Jennifer Bartlett, Lee Breuer, Richard Foreman, William Pope.L, William Wegman, gba lati se ise won ti ogunlogo awon enia ri. Ifihan tio je ti Franklin Furnace pelu awon iwe itan ti o lokiki; awon miran je ise ti ki ise fun pipe. Awon bi Fluxus abbi ise Russian Samizdot - awon yi je ise asehan ti a je ki o se iranti ohun apapo ti a o ma ranti fun igba pipe. Ni odun 2006, Franklin Furnace bere ajose pelu ARTstor, igbero awon ti Andrew W. Mellon Foundation, lati jeki awon ohun ti a ti kojo le se lo fun gbogbo agbaiye.

BUN FUN ISE AWON AYAWORAN

Ni ododun, Franklin Furnace ma npin ebun ti o je owo lati fi sise ni ona meji. Bkini ni Franklin Furnace Fund for Performance Art fun onise amuse ti onse iranlowo fun awon asere ti nwon se nru; eyi ma nfun won ni aye lati se ise ti o joju ni ilu New York Ekeji ni ilele fun ise lori "The Future of the Present" Ni ipase eyi ni awon ayaworan le da aworan lori Internet. Owo ebun fun ise lona mejeji bere lati ori egberun meji titi de egberun marun. A si gba awon ayaworan lati orile ede gbogbo ni iyanju lati bere iranlowow. E bere fun iranlowo ni ede oyinbo nikan.

Franklin Furnace ko ni alakoso ise aworan; lododun, awon akojopo ayaworan ma nfi ori kori lati wo ohun ti nwon yio se. Igbagbo wa nipe, awon elegbe bawon yi fun awon ayaworan lati orile ede gbogbo ni anfani lati le fi ise won han.

Bayi ni ase le bere fun iranlowo:

http://franklinfurnace.org/artists/index.php

Gbogbo awon ti o nbere fun iranlowo ni ao fun ni iranlowo. Ni ododun ni a ma nparo awon igbimo gege bi itumo awon ayaworan ti nwon. Se iforimule se ma nparo. Nitorina, ti ko ba bosi ni akoko, tun gbiyanju l'ekeji.

(D) E FI OWO KOWE FUN IFILO OSOSE LORI E-MAIL

Ohun ti o nlo lowolowo je ifilo osose ti Franklin Furnace ma ngbejade ni ede Gesi fun Egbegberun awon ti o nse akoso aworan yiya. Lati igba ti a ti bere re ni odun 2001, ohun Ti o nlo lowolowo nfun ni ni ifihan nipa isele ni agbegbe, ni gbogbo America ati ni gbogbo agbaiye nipa awon ayaworan ti won jeti Franklin Furnace ti igba tokoja ati ti isinsiyi pelu awon omo egbe Franklin Furnace. Iwo na le di ara Franklin Furnace nipa fifi oruko ati ibi ikowesi re sowo si mail@franklinfurnace.org Jeki a mo boya ayaworan ni e ati bi o se mo nipa wa. Jowo jeki a mo ibiti a ti le kowe si e ni ojo iwaju. Awa ti a wa ni Franklin Furnace a ki tu asiri alasiri. E se pupo.

Translated from English to Yoruba by Dr. Jide Ojo (April 22, 2007).